Tweet ògbufọ̀:
'العربية / Al-ʿarabīyah |
Ìtàn kẹ́rinKò mọ Ìjáfáfá tí Ó nílònípasẹ̀ Phil Bartle, PhDÌtúmọ̀ nípasẹ̀ Tóyìn Jẹ́nyọ̀Shamim ní ẹ̀bùn àmútọ̀runwá gẹ́gẹ́bí òsèré. Kò sì ipa tí kò le se nínú eré gẹ́gẹ́bí ipa tí eré bá ti nílò rẹ̀. Ní ìgbà tí ó bẹ̀rẹ̀ sí ṣètò àwùjọ, ó ri wípé àwọn ènìyàn àwùjọ yìí kò ní òye àwọn nkan kan, àìní omi tí ó mọ́, àìní ẹ̀kọ́ tí ó péye lóri ìmọ́tótó, àìní ọ̀nà tótọ́ láti da ẹ̀gbin nù. Bóyá wọ́n kò ní òye ní tòótọ́. Sùgbọ́n ohun tí kò mọ̀ ni pé tí ó bá báwọn sọ̀rọ̀ bíi ọlọgbọ́n sí òmùgọ̀, á mú wọn rìn jìnnà si, wọn kò sì ní nífẹ̀ẹ́ si mọ́. Ó se bẹ́ẹ̀ ní àkọ́kọ́, sùgbọ́n ó soríire pé ẹlẹgbẹ́ rẹ̀ sọ fun pé ó le è má a báwọn sọ̀rọ̀ gẹ́gẹ́bí ẹlẹgbẹ́ rẹ̀. Ó ní agbára láti lo àwọn ẹ̀bùn àmútọ̀runwá rẹ̀, ó kàn ní láti mọ̀ wipe yíò se àseyọrí si i tí ó bá báwọn sọ̀rọ̀ gẹ́gẹ́bí ẹlẹgbẹ́ rẹ̀. Ó tètè yí ìlànà rẹ̀ padà kí àwọn ènìyàn àwùjọ yìí má bá a rìn jìnnà si, ó sì tẹ̀síwájú láti se àseyọrí nínu ìsekóríyá tí ó se fún wọn láti tún ìlera wọn se nípa yíyọ ọ̀pọ̀lọpọ̀ ààrùn omi kúrò láàrin wọn. Àkíyèsí: Àwọn ítàn yìí kì í se àròsọ. A yí orúkọ àwọn ènìyàn àti abúlé padà nítorí ìdánimọ̀. ──»«──Tí o bá da ọ̀rọ̀ kọ láti orí ààyè ayélujára yìí, jọ̀wọ́ dárúkọ(àwọn) ònkọ̀wé |
ojú- ìwé àkọ́ọ́kàn |
Gbígbáradì |