Tweet ògbufọ̀:
'العربية / Al-ʿarabīyah |
Ìtàn kẹ́taKò mọ àwùjọ rẹ̀nípasẹ̀ Phil Bartle, PhDÌtúmọ̀ nípasẹ̀ Tóyìn Jẹ́nyọ̀Orí Andreas wú, ara rẹ̀ sì yá gaga. Ó ńlọ sí àwùjọ rẹ̀ àkọ́kọ́, láti lọ bẹ̀rẹ̀ isẹ́ gẹ́gẹ́bí olùsekóríyá àwùjọ “Mo fẹ́ kí wọ́n mọ̀ wipe ọ̀rẹ́ àti alábàsiṣẹ́pọ̀ wọn ni mo jẹ́” ó ńrò nínú ní ọkàn rẹ̀. Ó ńlọ káàkiri sí ọ̀dọ̀ àwọn ènìyàn abúlé tí Ó pàdé, Ó sì ńna ọwọ́ sí wọn láti bà wọ́n lọ́wọ́ àti ọkùnrin àti obìnrin. Ohun tí kò se àkíyèsí ni pé, nínú àwùjọ àwọn mùsùlùmí tí kò gbọ̀jẹ̀gẹ́ yìí, láti na ọwọ́ sí obìnrin láti bà lọ́wọ́ jẹ́ àbàwọ́n ní ara asọ ààlà rẹ̀, Ó tún jẹ́ ìfigagbága pẹ̀lú ọkọ rẹ̀. Andreas kò mọ ìdí tí àwọn ènìyàn yìí kò fi yọ̀ mọ́ òhun gẹ́gẹ́bí Óhun ti se sí wọn nígbàtí ó pàdé wọn. Bíótilẹ̀jẹ́pé ó se àtúnse níkẹhìn, àwọn ènìyàn kò gbàgbé ohun àbàwọ́n tí ó se nígbàtí ó kọ́kọ́ dé àwùjọ wọn. Àkíyèsí: Àwọn ítàn yìí kì í se àròsọ. A yí orúkọ àwọn ènìyàn àti abúlé padà nítorí ìdánimọ̀. ──»«──Tí o bá da ọ̀rọ̀ kọ láti orí ààyè ayélujára yìí, jọ̀wọ́ dárúkọ(àwọn) ònkọ̀wé |
ojú- ìwé àkọ́ọ́kàn |
Gbígbáradì |