Tweet ògbufọ̀:
ojú- ìwé mííràn:àkójọpọ̀-ẹ̀kọ́olùtọ́sọ́nán ààyè ayélujárakókó ọ̀rọ̀Olùbásọ̀rọ̀Àwọn ìwé tí ó wúlòÌsoópọ̀ tí ó wúlòẹ̀kọ́ nípa ẹ̀dá ènìyàn àti àsà rẹ̀ |
Ìtàn kàrúnKò mọ ìpìlẹ̀ àgbékalẹ̀nípasẹ̀ Phil Bartle, PhDÌtúmọ̀ nípasẹ̀ Tóyìn Jẹ́nyọ̀Paul kò kọbiara si ní ìgbàtí wọ́n ńjíròrò lóri ìpìlẹ̀ àgbékalẹ̀ lásìkò ìdánilẹ̀kọ́ olùsekóríyá rẹ̀. Kò mọ wípé fífi owó ránsẹ́ lẹ́ẹ̀kan kì í se ìpilẹ̀sẹ̀ (ìsẹ̀dá) owó wíwọlé tàbí ọrọ̀. Láàrin ọ̀sẹ̀ kínín tí ó dé papa, ó rí àwùjọ kan tí ó tòsì tóbẹ́ẹ̀gẹ́ tí ìfebipani àti ìjìyà farahàn láàrin wọn. Ó gbọ́ nípa ilé-isẹ́ kan tí ó ní owó, ó sì gba díẹ̀ níbẹ̀ fún otòsì. Ó sètò bí àwọn tí ó tòsì jùlọ nínú àwùjọ se rí ẹ̀bùn owó gbà, ọkàn rẹ̀ sì balẹ̀. Sùgbọ́n kò ì tíì dín òsì kù; ó kàn rọ̀ọ́ lójú díẹ̀ ni, ó mú ìrora rẹ̀ kúrò fún ìgbà díẹ̀. Lẹ́hìn osù mẹ́fà, gbogbo àpẹẹrẹ òsì ti tún farahàn lẹ́ẹ̀kansi, nítorí wọn ò fi bẹ́ẹ̀ ríjẹ ju ti àtẹ̀yìnwá lọ. Lẹ́hìn èyí, ó lọ fún ìdánilẹ̀kọ́ onífiọ̀rọ̀wéọ̀rọ̀ kan lẹ́nu isẹ́ ní ibi tí wọ́n ti jíròrò lórí ìyàtọ̀ tí ó wà láàrin wọn, ó kọ́ bí ó se le è darí àwọn ènìyàn àwùjọ láti sẹ̀dá ọrọ̀ nípa fífi iyì kun. Ó padà sí àwùjọ, ó sì fi hàn àwọn ènìyàn bí wọ́n se le sẹ̀dá ọrọ̀ nípa bíbẹ̀rẹ̀ òwò alábẹsékélé, lílo owó – àwìn alábẹsékélé, àti dídi olùsẹ̀dá ọrọ̀. Àwọn ènìyàn àwùjọ yìí soríire pé Paul setán láti kọ́ ẹ̀kọ́. Àkíyèsí: Àwọn ítàn yìí kì í se àròsọ. A yí orúkọ àwọn ènìyàn àti abúlé padà nítorí ìdánimọ̀. ––»«––Tí o bá da ọ̀rọ̀ kọ láti orí ààyè ayélujára yìí, jọ̀wọ́ dárúkọ(àwọn) ònkọ̀wé |
ojú- ìwé àkọ́ọ́kàn |
Gbígbáradì |