SE IDAMO AWON AFOJUSUN RE
Aseyori wo ni o fe se
Nipase Phil Bartle, Ojogbon
Ti a gbifo re lati owo o Adebunmi Adetona Amos
Iwe Idanileko
Erongba ati afojusun fun jije olusekoriya
Okan
ninu awon ede ipolongo ti a n lo fun idanileko awon giwa ni "Nigbati o ko ba mo ibi
ti o nlo, ibi gbogbo ni yio da bii oju ona ti o see to." (Wo
"Awon
Gbolohun Ipolongo.")
Eyi
nii se pelu iwo naa, paapaa, ti o ba ngbaradi fun sise koriya.
O
rorun lati ki ara bo opolopo ojuse, ki o si dabi enipe owo kun wa, ki a se eto fun
awon ipade, ki a ko ile ilosi, ki a maa ba awon olori ni awujo soro, ki a maa gbe
awon oluranlowo ni igbonwo, ki a maa ru awon eniyan soke lati mun ohun kan se, sugbon
ti o je pe a ko tesiwaju ninu afojusun wa lati fun awujo ni okun.
O
se pataki ki o koko jeki o di mimo, akoko fun ara re, ekeji lori iwe, ati eketa fun
awon ti o wa ni ayika re, ohun ti o je afojusun re
Nihin,
o gbodo bere si se akosile ninu iwe akosile re, tabi abala ti o ti seto fun akosile
awon afojusun ati igbekale re.
O
gbodo se igbekale won gege bi afojusun ti ara re gangan, lai maa ronu nipa won bii
awon erongba elomiran lasan.
Awon
afojusun lati ran awujo lowo le yato laarin enikan si enikeji ati laarin awujo kan
si omiran.
Sibesibe,
awon ohun ti o baramu wa.
Awon
eleyi ni: eto
lati fi opin si osi ati ise, eto
isejoba ti o dara,
ayipada ninu egbe, awujo imun
loo rin si fun iseese itesiwaju,
fifun awon ti owo oya won kere ati awon ti a ti fi eto won dun won ni okun sii, ati mimu
iye okunrin ati obirin se deede
Bi
o ti n tesiwaju ninu kika akosile yi, ti o si tun n kopa ninu akitiyan sise koriya,
oo se awari pe okookan ninu awon afojusun yi ni o ndun moni ti o si tun peni nija,bi
o ti n moo si.
Maa
pada loorokore sinu iwe akosile re liti fikun akosile re, ki o tun tun se, ati lati
se afikun fun awon afojusun re.
Fun
apare, eto lati din osi ati ise ku ma n ta koko o si ma n peninija nigba ti a ba
n sise le lori ju igba ti a n se akosile re lo.
A
n ko lati yago fun "lile osi ati ise sehin" nitoripe eleyi yio kan din irora ti osi
ati ise n mu wa ku ni, kii se ojulowo ona abayo patapata kuro ninu osi ati ise.
Osi
ati Ise rekoja
oro pe owo ko si lowo, (bi o o se awari nigbaose) ati pe gbigbogun ti orisun osi
ati ise tumo si gbigbogun ti ihuwasi
ko kan mi, ihuwasi
ope, arun,
ati etan.
Eyi
ni eyokan ninu awon apere bi imoye re nipa afojusun re yio se gbooro sii nipase iriri.
Nibakannaa,
eto isejoba ti o dara ko kuku tumo si pe idari ti o se takun-takun ati eto akoso
ti o munadoko.
O
tun tumosi kiko akoyawo, ilowosi awon eniyan, igbekele, jije olotito ati iran kedere
fun ojo iwaju.
Oo
ko eko, pelu, pe yio soro lati reti ki awon adari awujo je eniti
o nko akoyawo ni
ori eto lilo alumoni awujo ti iwo fura ara re ko ba ko akoyawo lori ninu akitiyan
re ni awujo.
Wo
ni: Akojopo
Itumo fun Awon Koko Oro,
fun iforo we oro akoko nipa awon afojusun wonyi (eto
lati din osi ati ise ku, imutesiwaju
awujo).
Fi won we awon akosile ninu iwe akosile re.
––»«––
Ti o ba se adako ohunkohun lati ihin yi, jowo fi oriyin fun eni (tabi awon) ti o koko se agbkale re ki o si tun pada wa fi ori re so cec.vcn.bc.ca/cmp/
© Ofin adako 1967, 1987, 2007 Phil Bartle lati owo Lourdes Sada
––»«––Atunko: 2012.03.18
|