Oju - iwe akookan
Titesiwaju awon ona - abayo
Ogbufo :

'العربية / al-ʿarabīyah
Bahasa Indonesia
বাংলা / Baṅla
Български език
Català
中文 / Zhōngwén
Deutsch
English
Español
Filipino/Tagalog
Français
Galego
Ελληνικά / Elliniká
हिन्दी / hindī
Italiano
日本語 / Nihongo
Kiswahili
Português
Română
Русский
Српски / Srpski
Tiếng Việt
Türkçe
اردو / Urdu
Èdè Yorùbá

                                        

Oju - iwe miran:

Awon Akojopo - eko

Olutosona aaye ayelujara

Koko oro

Olubasoro

Awon iwe - ipamo ti o wulo

Isoopo ti o wulo

Eko nipa eda eniyan ati asa re

EKO TI A KO

Ati Akiyesi Awon Ohun Ti O Seese Lati Tesiwaju

nipase Phil Bartle, PhD

itunmo nipase Toyin Jenyo


Iwe Idanileko

Bi awon olusekoriya se wa, ti won nsi awujo kookan sile, isopo ati itesiwaju gbodo wa laarin won; eko ti ikookan won ba ri ko gbodo je ara ajo iranti gbogbo ona - abayo won.

Awa eda - eniyan lee ko eko lati ara aseyori ati ikuna wa, lati ara awon aseyege ati awon asise. Ranti wipe awon asise yen, awon ikuna ati awon ajalu ko jo ara won.

Asise kan ki i se ikuna; lati se asise ni ti eniyan. Ikuna kan ki i se ajalu; ai le se aseyori ninu nkankan ko tumo si wipe o je ikuna. Ajalu kan ko tumo si opin aye tabi opin asiko. Nigba ti a ba subu a gbodo gbe ara wa dide ki a si tesiwaju. Ikookan ni a nyo ese ni ekuu

Ti o ba ti ni aseyori ni didari awujo kan lati ko ile - igbanse funrare, tabi pari awon erongba miran, nigba naa o ti gbe igbese kan sunmo igberale ara eni si i. Ko lee lo lai si iyonu tabi laisi abawon. Ti o ba ro wipe o lo bee, a je wipe o ko je olotito si ara re.

Se agbeyewo awon ilana ati ipa ti o ko ninu re. Ki o fi igboya ninu otito gba awon asise re. Ko agbeyewo isekoriya alayipo re sile. Ma se ojsaaju, ki o si ko ohun ti o ye nipa awon asise ati awon ikuna; mase lo won gegebi awawi lati so ara re daro pelu irewesi.

Lo gegebi eko lati ko; ti o wulo ti o si bojumu gidigidi ju eyi ti o le e ko ninu iwe - eko kika tabi iwe - ilana bi eyi. Lo iwe- akosile, lo agbeyewo re, lo eko ti o ko, lati dagba ninu okun ati imose si gegebi olusekoriya.

Se iru nkan be pelu, ati fun, awon awujo.

––»«––

© Ase 1967, 1987, 2007 Phil Bartle
Igbekale ayelujara nipase Lourdes Sada
––»«––
Imudojuiwon kehin: 2015.05.13

 Oju - iwe akookan

 Titesiwaju awon ona - abayo