Oju - iwe akookan
Titesiwaju awon ona - abayo

Ogbufo:

'العربية / al-ʿarabīyah
Bahasa Indonesia
বাংলা / Baṅla
Български език
Català
中文 / Zhōngwén
Deutsch
English
Español
Filipino/Tagalog
Français
Galego
Ελληνικά / Elliniká
हिन्दी / hindī
Italiano
日本語 / Nihongo
Kiswahili
Português
Română
Русский
Српски / Srpski
ไทย / Thai
Tiếng Việt
Türkçe
اردو / Urdu
Èdè Yorùbá

                                        

Oju - iwe miran:

Awon Akojopo - eko

Olutosona aaye ayelujara

Koko oro

Olubasoro

Awon iwe - ipamo ti o wulo

Isoopo ti o wulo

Eko nipa eda eniyan ati asa re

IDARI AWUJO ATI ISEKORIYA ABELE

Titesiwaju nipase Isekoriya Aladaase

nipase Phil Bartle, PhD

itunmo nipase Toyin Jenyo


Iwe Idanileko

Ohun ti o se gegebi olusekoriya je ona - abayo lati ita; ki idagbasoke to lee ma tesiwaju, awoju funrare ni lati ma seto ona - abayo siwaju si i

Kokoro lati te awon ona - abayo ti o ni se pelu sise afikun fun awujo lati lee gbekele ara won siwaju, wa ninu awujo. Ibewe re lee setan, won si lee ni agbara lati ropo re pelu elomiran, sugbon ilepa re ti o se pataki julo ni lati mu ki awujo tesiwaju ninu isekoriya funrare.

Ona ti o le fi se eyi ni lati da awon eniyan ninu awujo mo ti o ni abuda lati di olusekoriya, ati iwa ati imoye ti o ye lati ko won awon imose re, ati lati ko won bi won se ropo re lehin ti o ba fi ibe sile.

O fe funrare yo ara re kuro lenu ise.

Idagbasoke awujo je ona lati se ayipada fun awujo.O ko lee gbe awujo soke; awujo ni o le gbe ara re soke.

Ohun ti o lee je julo ni ayase ati imoriya fun iyipada awujo naa. Gegebi oro pataki lati enu Mwalimu Julius Nyerere, "A ko le gbe eniyan soke; eniyan ni yi o gbe ara re soke".

Tun ranti wipe irinse ati imose ti o ni lee je ayase ti o lagbara fun iyipada awujo. Nitorina, bi eyikeyi irinse, a lee silo. Nigati o ba da eniyan mo laarin awujo ti o lee ko leko lati ropo re, O se pataki lati se ayewo iwa re lati ri daju wipe yio lo irinse isekoriya fun iwulo awujo, ki yio si lo fun anfani arare laibikita fun awujo.

Mo wipe awon miran ni afojusun ti o ni nkan se pelu Oselu and ise - aje. Pelu ogbon ibasepo and imu nkan rorun ti o mu ina de oko, eniyan lee si isekoriya fun anfani arare. Woo leekansi Mo awon Imose ti o nilo ati afiwe awon "Onise Alagadagodo".Nigati o ba da eniyan ti o ni abuda isekoriya mo laarin awujo. Fi ara bale wo pule isora fun igba die. Ma kanju lati wa eniti yio ropo re; ni suuru lati se ohun ti o to

Nigbati o ba so fun egbe kan wipe ki won ni suuru ki won sise ohun ti o to, o le so itan kekere yii lati owo egbe onimalu ni Iwo - oorun Africa ti o da lori malu meji.

Malu meji nbo lati ori oke, won ri opolopo malu ni afonifoji niwaju won. Malu ti o kere wipe "Oh arakunrin baba mi, E je ki sare lo si isale ki a si se ise die. Malu ti o dagba da lohun wipe "Rara, je ka rora rin lo si isale ki a si se gbogbo ise

Ni suuru lati wa ati lati ko eni ti yio ropo re

Nigba ti o ba ti da enikan tabi awon awon eniyan die ti o ni abuda isekoriya mo, pelu ami - idayato bi otito, idari, ifokansi tooto fun idagbasoke awon eniyan, o nilo lati dawonleko. Ti won ba ni ife si, o le seto nkan bi " omo ekose," lati ni akoko ti o to lati se alaye fun won idi ti o fi se ohun ti o nse.

Pari gbogbo akori ti o wa ninu die ninu awon ipin akoko iwe - ilana yi i. Riran won lowo lati ko awon agbekale se pataki bi kiko nipa awon imose. Je ki won gbiyanju lati se kokari asiko ikoni loore koore. Sise kokari won ni lati posi bi imose won ba se ndagba si. Lehin ti won ba ti se agbo isekoriya kan tabi meji, won gbodo le maa se eto ikoni leyin re.

O wa ni oju ona lati mu ki isekoriya re tesiwaju

––»«––

© Ase 1967, 1987, 2007 Phil Bartle
Igbekale ayelujara nipase Lourdes Sada
––»«––
Imudojuiwon kehin: 2015.05.13

 Oju - iwe akookan

 Titesiwaju awon ona - abayo